SA GBEKELE

Ese: , 1887; a ko mo eni to se itumo si ede Yoruba.

Orin: .

Gba t’a b’Oluwarin ninu ‘mole oro re,
Ona wa yio ti ma mole to!
Gba t’a ban se’fe Re, on y’o ma ba wa gbe,
At’ awon t’o ba gbeke won le.

Egbe

Sa gbekele, ona miran kosi
Lati layo n’nu Jesu, jupe k’a gbekele.

Ko s’ohun to le de, loke tabi nile
Tole ko agbara re l’oju;
Iyemeji a’teru, ibanuje, ekun
Kole duro b’a ba gbekele.

Egbe

Ko s’eru t’ale ru, ko s’aro t’a le pin
Ti ki y’o san ere re fun wa
Kosi arokan mo, tabi ifajuro
Sugbon ibukun b’aba gbekele.

Egbe

A ko le f’enu so b’ife re ti po to
Titi a o f’ara wa rubo
Aanu ti o nfihan, at’ayo t’o nfun ni
Je t’awon to ba gbeke won le.

Egbe

Nibi ‘pade ayo ka joko ni ese Re.
Tabi kajo rin ni ona Re.
Oun to so la o se, ibi to wu la o lo;
Kosi beru, ka sa gbekele.

Egbe